All African People's Consulate
Jumuiya ya Watu wa Kiafrika Wote
Awujọ Gbogbo Awọn Africa
مجتمع جميع الشعوب الأفريقية
Ẹ káàbọ̀ sí ilé-iṣẹ́ aṣojú gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà—Venice.
Ilé-iṣẹ́aṣojúgbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà ti Venice wà ní:
Castello, 1636, 30122 Venezia VE, ItalyIlé-iṣẹ́aṣojúgbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà ni ilé-iṣẹ́ aṣojúàwùjọgbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà (tí a dá sílẹ̀ ní March 8, 2031). Ó wà láti pèsè àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfríkà àti àwọn ọmọ ìran Áfríkà tí wọ́n ń gbé ní Ítálì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ ara àwùjọ àgbáyé wa tí wọ́n ń bẹ̀ wà wò. Lára àwọn iṣẹ́ wa, a pèsè ìwé ìrìnnà gbogboàwùjọilẹ̀ Áfríkà fún àwọn ará Áfríkà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà. A tún máa ń mú kí pàṣípààrọ̀ àṣà àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí kì í ṣe ara àwùjọ náà rọrùn. Àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ ṣèbẹ̀wò lè bèèrè fún ìwé ìwọ̀lú. Àlàyé nípa bí a ṣe lè bèèrè fún àti gba ìwé ìrìnnà rẹ tàbí ìwé ìwọ̀lú rẹ wà ní aaye ayelujara ilé iṣẹ́ aṣojú wa ni apa ibi ti ìwé ìrìnnà àti ìwé ìwọ̀lú wa.
A pèsè ìsopọ̀ àti àwùjọ fún gbogbo ènìyàn. Igbekale ilé-iṣẹ́ aṣojú ni ero ati imisi tí Dread Scott ṣe.
Àwọn iṣẹ́ aṣojú, ìwé ìrìnnà àti ìwé ìwọ̀lú
Áfríkà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ aráyé- ọjọ́ iwájú agbayé. Ẹ káàbọ̀ sí ilé.
Ilé-iṣẹ́ aṣojú gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkàńmú kí pàṣípààrọ̀ àṣà rọrùn ní àwùjọ wa àti ní àwùjọ mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí apá kan iṣẹ́ yìí a máa ń fún àwọn ènìyàn to ṣe àṣeyọrí ní ìwé ìrìnnà àti ìwé ìwọ̀lú won.
Gbogbo àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfríkà àti àwọn ìran Áfríkà, láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí, jẹ́ araàwùjọgbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà kárí ayé wa, a sì gbà wọ́n lálejò láti beere fún ìwé ìrìnnà. Àwọn mìíràn ni a gbà níyànjú láti bèèrè fún ìwé ìwọ̀lú.
Láti ìgbà tí a ti dá gbogboàwùjọàwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfríkà sílẹ̀, ní March 8, 2031, ìrìn-àjò tí kò ní ààlà àti tí kò ní ìforígbárí ni a ti fi dáni lójú láàrin àwùjọ – ní ilẹ̀ Áfríkà àti ní àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè tí wọ́n ti darapọ̀ mọ́ àwùjọ náà.
Olukuluku gbọdọ yọju ní ilé-iṣẹ́ aṣojú fun ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìrìnnà àti ìwé ìwọ̀lú. Àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìforúkọsílẹ̀ lè ṣe ìforúkọsílẹ̀ (nípa lílo fọ́mù ìforúkọsílẹ̀) tàbí kí wọ́n kàn wọlé kí wọ́n sì ṣe ìforúkọsílẹ̀ ní ilé-iṣẹ́ aṣojú lásìkò ṣíṣí. Àwọn ènìyàn tí wọ́n yàn ọjọ́ fún ni wọ́n máa fi sí ipò kìíní ju àwọn tí wọ́n kò yan ọjọ́ fún.
Hours of Wákàtí iṣẹ́: April 20, 2024 – April 28, 20204, Tuesday – Sunday 10am – 7pm
April 30, 2024 – September 29, 2024, Thursday – Sunday 11am – 7pm
A pèsè ìsopọ̀ àti àwùjọ fún gbogbo ènìyàn. Igbekale ilé-iṣẹ́ aṣojú ni ero ati imisi tí Dread Scott ṣe.
ṢE IGBAGBÜ LATI BEERE FUN VISA TABI IWE IRINNA:
Èyí ni àwùjọ rẹ. O lẹ́ bẹ̀ wa wò kí o sì dúró láti darapọ̀ mọ́ ìjíròrò tí ó ń lọ ní àyíká to rọrùn.
Olubasọrọ
Wákàtí iṣẹ́: April 20, 2024 – April 28, 20204, Tuesday – Sunday 10am – 7pm
April 30, 2024 – September 29, 2024, Thursday – Sunday 11am – 7pm
Adirẹsi ojúkojú: Castello, 1636, 30122 Venezia VE, Italy.
Imeeli: staff@allafricanpeoples.org